Ìmọ̀ sáyẹ́nsì ti fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé tí ènìyàn tó bà ń gbé pẹ̀lú àrùn HIV bá wà ní ipò àìrí, wọ́n máa ń wà ní ìlera pípé, wọn kò sì tún lè darí àrùn HIV yìí sí ẹlòmíràn. Oun tí a ń pè ní Ipò Àìrí = Kò Lè Pín Kárí (U=U).
Eléyìí jẹ́ ìròyìn tó ṣe pàtàkì gidi ní ìtàn àrùn HIV. Ó túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn tó ń gbé pẹ̀lú àrun HIV ni ipò àìrí yìí ní láti má bẹ̀rù pé wọ́n lè pín-in fún àwọn tí wọ́n ń bá lòpọ̀. Àwọn ènìyàn tó ń gbé pẹ̀lú àrun HIV ni wọ́n jẹ́ ara ojútùú sí mímú òpin wá sí àrun HIV nípa lílo òògun wọn kí wọ́n baà lè wà lálàáfíà.
Lọ sí www.uequalsu.org. (Ibi tí ẹ ti lè kà síi ní èdè òyìnbó)