HIV jẹ́ kòkòrò tí ó máa ń mú ẹ̀ṣọ́ ara dínkù. HIV máa ń mú àwọn olúṣọ́ ara rẹ̀wẹ̀sì, ó sì máa ń jẹ́ kí ó nira fún ara rẹ láti wà lálàáfíà. Bí HIV ṣe ń gbòòrò síi, ó le di oun tí a ń pè ní Ààrùn Èèdì (AIDS).
Oun tó ń mú'nú ẹni dùn ni wípé àwọn òògùn tó péyeé wà láti mú àwọn ẹ̀ṣọ́ ara dúró. Ti o bá ti bẹ̀rẹ̀ òògùn ẹ ní kíákíá, tí o sì ń lòó déédé, ọwọ́ rẹ á ká HIV. A ti ṣe àṣeyọrí púpọ̀ nípa àìsàn yìí, a sì tún ń ṣe síi. Lónìí, àwọn tó ní HIV le gbé ilé ayé bíi àwọn tí kò ní, bí wọ́n bá ṣá ti ń lo òògùn wọn.
Yẹ fídíiò oní ìṣẹ́jú kan yìí wò láti Greater Than AIDS fún ẹ̀lúnrẹ́rẹ́. (Ibi tí ẹ ti lè kà síi ní èdè òyìnbó)