Àwọn ẹ̀nìyàn tó ní àrùn HIV máa ń ṣàyẹ̀wo iye kòkòrò tó wà nínú ẹ̀jẹ wọn nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìwòsàn pẹ̀lu dókítà. Dókítà yìí ni yóò fún wọn ní ìlànà fún àwọn àyẹ̀wò mìíràn lọ́jọ́ iwájú.
Nígbà tí ènìyàn bá ti wà ní ipò àìrí fún bíi oṣù mẹ́fà, a máa ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n yẹ iye kòkòrò tó wà nínú ẹ̀jẹ wọn wò ní oṣù mẹ́fà mẹ́fà.
Lọ sí HIV.gov fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé. (Ibi tí ẹ ti lè kà síi ní èdè òyìnbó)