Fífẹnukunu, fífọwọ́ kan ara ẹni lábẹ́ papọ̀, àti fífi ọwọ́ kan ara ẹni láti ara aṣọ, kò mú ewu àrùn HIV dáni. Fífi ẹnu ṣe ìbáṣepọ̀, lílá ìdí, bíbánisùn lókè àti nísàllẹ̀ pẹ̀lú rọ́bà ìdáàbòbò ni ó ní ewu HIV kékeré. Bíbánisùn látòkè láìlo rọ́bà ìdáàbòbò ni ewu tó pọ̀ díẹ̀ láti kó HIV, sùgbọ́n bíbánisùn ní ìsàlẹ̀ láìlo rọ́bà máa ń ní ewu púpọ̀.
Eléyìí ń jọ pọ̀ mọ́ HIV nìkan. Kìí ṣe fún àwọn àrùn STD mìíràn bíi sypphilis, gonorrhoea, chlamydia, tàbi hepatitis.