Ìdáhùn ìbéèrè yìí le díẹ̀. Fún àwọn kan, ó le léwu láti jáde wá sọ òtítọ́ fún dókítà, papàá jùlọ ní àwọn ìlú tí ó ti lòdì s'ófin láti jẹ́ ènìyàn LGBT, tàbí níbi tí òfin kò ti dáàbòbò ìjíròrò tó bá ṣẹlẹ̀ láàrín dókítà àti aláìsàn.
Ṣùgbọ́n, ti a bá le gbẹ́kẹ̀lé àwọn dókítà wa, wọn á lè tọ́jú wa dáadáa. Bíbáwọn sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí a jẹ́ lọ́nà ìbáṣepọ̀, lọ́nà ọkùnrin-sóbìnrin, àti irú ìbálòpọ̀ tí a ń ní ni yóò jẹ́ kí wọ́n mọ irú àyẹ̀wò tí a ní láti mú ẹ wà ní àláfíà.
Rántí pé o ní ẹ̀tọ́ sí ìjíròrò lọ́dọ dókítà tí kò léwù tí kò sì ní ojútì. Tí dókítà rẹ bá gbìyànjú láti sọ fún ẹ pé ọ̀nà ìbáṣepọ̀, tàbí ọ̀nà igbéléayé gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin/obìnrin, tàbí irú ìbálòpọ̀ tí o ń ní kò dára, sọ fún wọn pẹ̀lú ọ̀wọ̀ pé ọ̀rọ̀ oògùn nìkan lo fẹ́ sọ ní ọjọ́ àbẹ̀wò yìí.
Yẹ fídíò oní ìṣẹ́jú kan yìí wò, tí ó wá láti Greater Than AIDS láti mọ̀ síi. (Ibi tí ẹ ti lè kà síi ní èdè òyìnbó)