Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí yóò dá lé irú ìbálòpọ̀ tí o ń ní. Dókítà yóò ní láti yẹ̀ ẹ́ wò fún HIV, ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ fún syphilis, àti àyẹ̀wò ìtọ̀ fún STD nínú ǹkan ọmọkùnrin/ọmọbìnrin rẹ. Tí o bá ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnu, o ní láti ríi pé dókítà rẹ fi irinṣẹ́ rẹ̀ kó ẹnu rẹ láti wá STD níbẹ̀. Tí o bá sì jẹ̀ ìsàlẹ̀, o ní láti ríi pé wọ́n yẹ ihò ìdí rẹ náà wò.
Ó tún ṣe pàtàkì láti ṣe àyẹ̀wò fún Hepatitis B bó tiẹ̀ ṣe ẹ̀èkan péré, àti fún Hepatitis C, papàá jùlọ tí o bá ní àrùn HIV.
Yẹ fídíò oníṣẹ̀jú kan yìí wò láti Greater Than AIDS fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (Ibi tí ẹ ti lè kà síi ní èdè òyìnbó)