Ènìyàn wà ní ipò àìrí tí wọ́n bá ni àrùn HIV tí wọ́n sì ń lo àwọn òògùn wọn dáadáa débi wípé kòkòrò àrùn yìí ti lọ sílẹ̀ pátápátá lára wọn. Kódà, ó ti lọ sílẹ̀ débi pé àyẹ̀wò kankan kò ní fi kòkòrò àrùn yí hàn nínú ẹ̀jẹ wọn.
Ìmọ̀ sáyẹ́nsì ti fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé tí ènìyàn tó bà ń gbé pẹ̀lú àrùn HIV bá wà ní ipò àìrí, wọ́n máa ń wà ní ìlera pípé, wọn kò sì tún lè darí àrùn HIV yìí sí ẹlòmíràn. Oun tí a ń pè ní Ipò Àìrí = Kò Lè Pín Kárí (U=U).
È̀nìyàn lè wà ní ipò àìrí yìí fún ìgbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́, bí wọ́n bá ṣá ti ń lo òògùn wọn bí a ṣe ṣèto rẹ̀.
Wíwà ní ipò àìrí kò túmọ̀ sí pé ẹ̀ni yìí ti borí àrùn HIV, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀nà tó dájú láti dèna rẹ̀.
Àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú HIV ni wọn kò ní kòkòrò wọn ní ipò àìrí. Àwọn náà lè ṣe ìbálòpọ̀ lọ́nà tí kò léwu nípa lílo àwọn adènà HIV bíi rọ́bà ìdáàbòbò àti PrEP.
Lọ sí TheBody tàbí www.UequalsU.org fún àlàyé kíkún. (Ibi tí ẹ ti lè kà síi ní èdè òyìnbó)